Ní Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ náà
Gbogbo rẹ̀ ní àkókò kan, l’ọ́duń mélòó sẹ́yìn,
Èmi ọmọkùnrin náà tí mo di àgbà:
Lójijì ni ìgbésí ayé mi bẹ̀rẹ̀!
Mo rí àgbayé níwájú mi— Nítorí náà
Ọkùnrin òntúlẹ̀ náà ní ẹ̀gbẹ́ èèkàn àwọn ẹṣin rẹ̀,
Ń làágùn ní ẹ̀bá òkè rẹ̀ àkọkọ́,
Lẹ́hìn tí ó kúrò lẹ́ba àwọn erékùṣù
Gbẹ́ kòtò ní àfonifojì nísàlẹ̀,
Tí ó sì rí àwọn òkè ńlá láti máa ṣe ìtúlẹ̀,
Akọ àpáta tí yóò pa ẹnu ohun ìgóko rẹ̀,
Àrá ń rọ̀ lójú afẹ́fẹ́,
Àti pé ténté dúdú tí ó wà l’ókè rẹ̀, ti dán,
Ń dúró báyi.
—Jẹ́kí ó túlẹ̀ bí ó bá láyà!